Luke 9:22-27

22 aÓ sì wí pé, “Ọmọ ènìyàn yóò jìyà ohun púpọ̀, a ó sì kọ̀ ọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn alàgbà, olórí àlùfáà àti láti ọ̀dọ̀ àwọn akọ̀wé, a ó sì pa á, ní ọjọ́ kẹta a ó sì jí i dìde.”

23 bÓ sì wí fún gbogbo wọn pé, “Bí ẹnìkan bá ń fẹ́ láti máa tọ̀ mí lẹ́yìn, kí ó sẹ́ ara rẹ̀, kí ó sì gbé àgbélébùú rẹ̀ ní ọjọ́ gbogbo, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn. 24 cNítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ gba ọkàn rẹ̀ là, yóò sọ ọ́ nù: ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ ọkàn rẹ̀ nù nítorí mi, òun náà ni yóò sì gbà á là. 25Nítorí pé èrè kín ni fún ènìyàn, bí ó jèrè gbogbo ayé, tí ó sì sọ ara rẹ̀ nù tàbí kí ó fi ṣòfò. 26 dNítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá tijú mi, àti ọ̀rọ̀ mi, òun ni ọmọ ènìyàn yóò tijú rẹ̀ nígbà tí ó bá dé inú ògo tirẹ̀, àti ti baba rẹ̀, àti ti àwọn angẹli mímọ́.

27 e “Ṣùgbọ́n èmi wí fún yín nítòótọ́, ẹlòmíràn dúró níhìn-ín yìí, tí kì yóò rí ikú, títí wọn ó fi rí ìjọba Ọlọ́run.”

Copyright information for YorBMYO